Daniẹli 12:1
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ìgbà ìkẹyìn
12 (A)“Ní àkókò náà, ni Mikaeli, ọmọ-aládé ńlá, ẹni tí o ń dáàbò bo àwọn ènìyàn an rẹ̀ yóò dìde. Àkókò ìpọ́njú yóò wà, irú èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ rí láti ìbẹ̀rẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè títí di àkókò náà. Ṣùgbọ́n ní àkókò náà àwọn ènìyàn rẹ̀, gbogbo àwọn tí a bá ti rí orúkọ wọn nínú ìwé ni a ó gbàlà.
Read full chapter
Gẹnẹsisi 49:11
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
11 Yóò má so ọmọ ẹṣin rẹ̀ mọ́ igi àjàrà,
àti ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ mọ́ ẹ̀ka tí ó dára jù.
Yóò fọ aṣọ rẹ̀ nínú wáìnì
àti ẹ̀wù rẹ̀ nù nínú omi-pupa ti èso àjàrà (gireepu).
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.