Deuteronomi 25:13-16
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
13 (A)Má ṣe ní oríṣìí ìtẹ̀wọ̀n méjì tó yàtọ̀ sí ara wọn nínú àpò rẹ: ọ̀kan wúwo àti ọ̀kan fífúyẹ́. 14 Má ṣe ní oríṣìí ìwọ̀n méjì tí ó yàtọ̀ sí ara wọn ní ilé è rẹ: ọ̀kan fífẹ̀, ọ̀kan kékeré. 15 O gbọdọ̀ ní ìtẹ̀wọ̀n àti òṣùwọ̀n pípé àti ti òtítọ́ nítorí náà kí ìwọ kí ó lè pẹ́ ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fún ọ. 16 Nítorí Olúwa Ọlọ́run kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe nǹkan wọ̀nyí, àní ẹnikẹ́ni tí ń ṣe àìṣòdodo.
Read full chapter
Òwe 20:10
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
10 Ìwọ̀n èké àti òṣùwọ̀n ìrẹ́jẹ
Olúwa kórìíra méjèèjì.
Esekiẹli 45:10
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
10 Kí ẹ̀yin kì ó lo òṣùwọ̀n tó tọ́ àti efa títọ́ àti bati títọ́.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.