Kolose 2:2
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
2 Ohun tí mo ń béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fún un yín nínú àdúrà mi ni pé, kí a lè mú yín lọ́kàn le, kí a sì lè so yín pọ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ to lágbára, kí ẹ le ní àṣírí ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run lẹ́kùnrẹ́rẹ́. Àṣírí ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run náà ni Kristi fúnrarẹ̀.
Read full chapter
1 Tẹsalonika 2:10
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
10 Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí wà, bẹ́ẹ̀ náà sì ni Ọlọ́run pẹ̀lú, bí a ṣe gbé ìgbé ayé mímọ́, òdodo àti àìlẹ́gàn láàrín ẹ̀yin tí ó gbàgbọ́.
Read full chapter
1 Kọrinti 4:16
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
16 Nítorí náà mo bẹ̀ yín, ẹ máa ṣe àfarawé mi.
Read full chapter
1 Kọrinti 11:1
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
11 1 (A)Ẹ máa tẹ̀lé àpẹẹrẹ mi, gẹ́gẹ́ bí èmi náà ti ń tẹ̀lé àpẹẹrẹ Kristi.
Read full chapter
Ìṣe àwọn Aposteli 17:5-10
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
5 Ṣùgbọ́n àwọn Júù jowú, wọn sì fa àwọn jàgídíjàgan nínú àwọn ọmọ ènìyàn mọ́ra, wọ́n ko ẹgbẹ́ jọ, wọ́n sì ń dá ìlú rú; wọ́n sì kọlu ilé Jasoni, wọ́n ń fẹ́ láti mú Paulu àti Sila jáde tọ àwọn ènìyàn lọ. 6 Nígbà tí wọn kò sì rí wọn, wọ́n wọ́ Jasoni, àti àwọn arákùnrin kan tọ àwọn olórí ìlú lọ, wọ́n ń kígbe pé, “Àwọn wọ̀nyí tí o tí dorí ayé kodò títí de ìhín yìí pẹ̀lú. 7 Àwọn ẹni tí Jasoni gbà sí ọ̀dọ̀: gbogbo àwọn wọ̀nyí ni o sí ń hùwà lòdì sí àṣẹ Kesari, wí pé, ọba mìíràn kan wà tí í ṣe Jesu.” 8 Àwọn ènìyàn àti àwọn olórí ìlú kò ní ìfọ̀kànbalẹ̀ nígbà tí wọ́n gbọ́ nǹkan wọ̀nyí. 9 Nígbà tí wọ́n sì gbà onídùúró lọ́wọ́ Jasoni àti àwọn ìyókù, wọ́n fi wọ́n sílẹ̀ lọ.
Ní Berea
10 Lọ́gán àwọn arákùnrin sì rán Paulu àti Sila lọ ṣí Berea lóru. Nígbà tí wọ́n sí dé ibẹ̀, wọ́n wọ inú Sinagọgu àwọn Júù lọ.
Read full chapter
Ìṣe àwọn Aposteli 13:52
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
52 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn si kún fún ayọ̀ àti fún Ẹ̀mí Mímọ́.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.