Marku 4:33-34
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
33 Òun lo ọ̀pọ̀ irú òwe wọ̀nyí láti fi kọ́ àwọn ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí wọ́n bá ti ń fẹ́ láti ní òye tó. 34 (A)Kìkì òwe ni Jesu fi ń kọ́ àwọn ènìyàn ní ẹ̀kọ́ ìta gbangba rẹ̀. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí, nígbà tí ó bá sì wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, òun a sì sọ ìtumọ̀ ohun gbogbo.
Read full chapter
Johanu 10:6
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
6 (A)Òwe yìí ni Jesu pa fún wọn: ṣùgbọ́n òye ohun tí nǹkan wọ̀nyí tí ó ń sọ fún wọn kò yé wọn.
Read full chapter
Johanu 16:25
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
25 (A)“Nǹkan wọ̀nyí ni mo fi òwe sọ fún yín: ṣùgbọ́n àkókò dé, nígbà tí èmi kì yóò fi òwe bá yín sọ̀rọ̀ mọ́, ṣùgbọ́n èmi ó sọ nípa ti Baba fún yín gbangba.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.